Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2023

Question 4

  1. Lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ wọ̀nyí láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ onímọ́fíìmù méjì
  2. à-
  3. a-
  4. ọ̀-
  5. ì-
  6. i-


(b)           Lo ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀rọ̀-orúkọ tí o ṣẹ̀dá ní 4(a) ní gbólóhùn láti fi ìtumọ̀ rẹ̀ hàn

Candidates were required to use each of the given prefixes to derive two morpheme nouns in (a) and use each of the derived nouns in illustrative sentences.

            Lílo àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ láti fi ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ onímọ́fíìmù méjì àti ìlò wọn nínú gbólóhùn

           


S/N

Àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀

Ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá

Gbólohùn tí ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá wà nínú rẹ̀

i

à

àjọ, àlọ, àsè, àbọ̀, àṣẹ, àsé, àlọ́, àrùn.

Àjọ ojúmọ́ ni mò ń dá.
Ilé-iṣẹ́ àjọ Elétò ìdìbò ni Olú ti ń ṣiṣẹ́.
Àlọ yín á dára, àbọ̀ á sunwọ̀n.
Ìjàpá lọ jẹ àsè ní ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Wọ́n pa àṣẹ pé kí onílé gbélé
Bọ́lá fẹ́ràn láti máa bẹ́ àsé fún àwàdà ṣíṣe

ii

a

adé, ajọ̀, asẹ́, asọ̀, afọ̀, ayọ̀, ata.

Ọba dé adé.
A fi ajọ̀ jọ èlùbọ́ tí a fẹ́ẹ́ fi ro àmàlà.
Màmá Bọ́lá fi asẹ́ sẹ́ ògì.
Wọ́n ń ṣe asọ̀ nípa sísan owó-orí.
A lè fi ọ̀rọ̀ ṣe afọ̀.

iii

ọ̀

ọ̀mu, ọ̀pọ̀, ọ̀gbìn, ọ̀wọ́n, ọ̀hun, ọ̀ta, ọ̀dẹ̀

Ọ̀mu náà parí kèǹgbè ẹmu méjì lójú ẹsẹ̀.
Àsikò ọ̀pọ̀ oúnjẹ ni a wà yìí.
Iṣẹ́ ọ̀gbìn kòkó ni bàbá Mojísọ́lá ń ṣe.
Ọ̀wọ́n gógó epo bẹtiró ti gbòde kan.
Bí ó bá gba ìdọ̀bálẹ̀ bàbá rẹ̀, a jẹ́ pé ó ti jẹ ọ̀hun.

iv

ì

ìlù, ìfẹ́, ìkẹ́, ìgẹ̀, ìrìn, ìjà, ìtọ̀, ìsun, ìbọ, ìṣe, ìwẹ̀, ìlu, ìtẹ́.

Ìlù dùndún ni à ń lù fún egúngún aláré.
Bàbá àgbà fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ tó gbọ́ tirẹ̀.
Màmá àgbà ń ṣe ìkẹ́ àti ìgẹ̀ àwọn ọmọọmọ rẹ̀.
Ìrìn ọjọ́ kan gbáko ni àbúlé wa sí Ọ̀jọ̀ọ́.

v

i

ijó, ikú, itẹ́, isó

Ijó pákáleke ni à ń jó sí ìlù bàtá.
Ikú dóró, ó mú ẹni rere lọ.
Wọ́n gbé òkú lọ sí itẹ́ lẹ́yìn àdúrà fún òkú.
Isó inú ẹ̀kú, àmúmọ́ra ni.

             

Only a few of the candidates who tackled this question were able to use the prefixes to derive two morpheme nouns and use them correctly in illustrative sentences.