Question 10
Nínú ewì “Ẹ̀san” irú àwọn ènìyàn wo ni akéwì kìlọ̀ fún pé kí wọ́n ṣọ́ra nítorí pé ẹ̀san kò gbóògùn?
Observation
Candidates were required to mention the various sets of people warned in the poem against the consequences of their behaviour.
Àwọn tí akéwì kìlọ̀ fún pé kí wọ́n ṣọ́ra nítorí pé ẹ̀san kò gbóògùn ni:
- Ẹni tí ó dá àwọn tí ń bẹ níwájú rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ dùbúlẹ̀ àìsàn nítorí kí ó lè gba ipò wọn/afèrúgbàbùkún (A-fi-èrú-gbà-ìbùkún).
- Òǹpèdè/ ìkà ènìyàn/Alágàádágodo ọ̀ràn tí kò fẹ́ kí ẹlòmíràn gba iyì bí òun.
- Olóṣùnwọ̀n èké/Ẹni tí ó tajà eèpẹ̀/Oníkòlòbó ọ̀ràn/Aláparútu/Adàlúrú-pọ̀-mọ́-ṣàpà.
- Àwọn tí wọ́n ń jí owó ìlú kó pamọ́.
- Atafà-sókè-yídó-borí.
- A-jùkò-sọ́jà.
- Oníṣẹ́ burúkú.
- Ìyàwó tó sọ ọkọ rẹ̀ di ọ̀dẹ̀/dìndìnrìn.
- Onírìbá/Ẹni tí ó ń gba ẹ̀gúnjẹ.
General guesses were made on various sets of people warned and not as evident in the text.