Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2019

Question 8

Ṣàlàyé àwọn àǹfààní tí ìṣípà ọdẹ máa ń mú wá.

 

Observation

 

Candidates were required to explain the advantages of ‘Ìṣípà’ a traditional rite performed for a dead hunter.
Àwọn àǹfààní tí ìṣípà ọdẹ máa ń mú wá:
(i)         Wọ́n gbàgbọ́ pé ó máa ń mú kí àlàáfíà wà fún ọdẹ tó kú lọ́run nítorí pé wọ́n ti yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ẹgbẹ́ ọdẹ ti ayé.
(ii)        Wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé yóò mú ìrọ̀rùn bá àwọn ọmọlóòkú láyé.
(iii)       Lẹ́yìn ìṣípà ọdẹ ni àwọn ọmọlóòkú tó lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pé inú òkú yóò dùn sí wọn lọ́run.
(iv)       Lẹ́yìn ìṣípà ọdẹ ni àwọn ọmọlóòkú tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé “ó di ọwọ́ bàbá wọn lọ́run”, nígbà tí wọ́n bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún àṣeyege nǹkan.
(v)        Àwọn ọmọlóòkú yóò lè ní àǹfààní láti máa lọ sí ojú sàréè/orórì bàbá wọn fún píparí ìjà tí ó bá wà láàrin ẹbí wọn.
(vi)       Àwọn ọdẹ máa ń gba agbára ọ̀tun níbi orò ìṣípà ọdẹ.
(vii)      Àwọn ọdẹ yóò lè máa rí ojú rere Ògún nínú iṣẹ́ ọdẹ wọn.
(viii)     Òkú alára yóò máa ti àwọn ọdẹ lẹ́yìn, kò níí jẹ́ kí wọ́n ríjà Ògún nígbó ọdẹ.
(ix)       Ó fún òkú ọdẹ láǹfààní láti wá bẹ ilé ayé wò.
(x)        Òkú ọdẹ yóò ní àǹfààní láti wá mójú tó nǹkan rẹ̀.
(xi)       Gbogbo òògùn òkú ọdẹ yìí tí a kó mọ nǹkan orò ìpà yòókù kò níí jẹ́ kí nǹkan burúkú lè máa ṣẹlẹ̀ láàrin ilé.
(xii)      A máa ń gbọ́ ìtàn àtayébáyé nínú orin ìrèmọ̀jé Ògún tí a ń kọ́ níbi orò ìṣípà.
(xiii)     Púpọ̀ ènìyàn ni yóò di àmùrè láti ṣe ohun akíkanjú láyé kí àwọn náà tó papò dà, bí wọ́n bá ti gbọ́ nǹkan akíkanjú tí ọdẹ tí ó kú ti ṣe tí a fi ń ṣe ìrántí rẹ̀.
(xiv)     Orò ìṣípà ọdẹ máa ń pèsè àríyá ńlá fún ará àdúgbò, ẹbí, ará, ọ̀rẹ́, ẹgbẹ́ ọdẹ àti àwọn mo-yà-wá-wòran (ọdẹ) pẹ̀lú.
(xv)      Ó jẹ́ ọjọ́ ìkọ́ṣẹ́ ìrèmọ̀jé sísun láàrin àwọn ìjàdẹ/ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìrèmọ̀jé sísun.

          Most candidates who attempted this question made general guesses at advantages of oral literature instead of the advantages of the specific special traditional rite for a dead hunter, this amounted to poor performance in question 8.