Question 13
Ṣàlàyé èèwọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òrìṣà wọ̀nyí.
Observation
Candidates were tasked to explain the taboo for each of the deities in Yorùbá traditional religion.
Èèwọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Òrìṣà:
- Ọya: i. Awọn ọlọ́ya kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹran àgbò; wọn kò sì gbọdò sin àgbò.
ii. Irun àgùntàn kò gbọdọ̀ bọ́ sílẹ̀ ní ojúbọ Ọya.
iii. Àwọn Ọlọ́ya kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹran ajá.
- Ṣàngó:i. Kì í jẹ ẹran èsúró (èsúó).
ii. Kì í jẹ eku àgó.
iii.Kì í jẹ ẹ̀wà sèsé.
iv.Àwọn oníṣàngó kò gbọdọ̀ fá irun orí wọn.
- Ọbàtálá:i. Ọlọ́bàtálá kò gbọdọ̀ mu ẹmu.
ii. Àwọn àwòrò rẹ̀ kò gbọdọ̀ ru ẹ̀kú eégún.
iii.Ọlọ́bàtálá kò gbọdọ̀ jẹ iyọ̀.
iv. Ọbàtálá àti àwọn àwòrò rẹ̀ kò gbọdọ̀ jẹ epo.
v. Òrìṣà yìí àti àwọn abọrẹ̀ rẹ̀ kì í mu ọtí ṣẹ̀kẹ̀tẹ́ (ọtí tí a fi
àgbàdo pọn)
vi. Ọbàtálá kì í jẹ ajá.
vii. Ọbàtálá kì í jẹ ẹlẹ́dẹ̀.
viii. Ọbàtálá kì í mu omi ìkàsì (omi ọjọ́ kejì).
ix. A kò gbọdọ̀ tan iná dé ojúbọ Ọbàtálá.
- Orò: i. Obìnrin kò gbọdọ̀ fi ojú kan Orò.
ii. Wọn kò gbọdọ̀ fi orógbó bọ Orò.
iii.Wọn kì í fi ẹja bọ Orò.
iv.Ènìyan kò gbọdọ̀ rí àjẹkù Orò (ewé/ẹ̀ka igi tí Orò bá pa).
v. Àwọn onílù kò gbọdọ̀ lu ìlù ní àsìkò ọdún Orò.
(ẹ) Ṣànpọ̀nná:i. Bí òòrùn bá mú hanrínhanrín, ènìyàn kò gbọdọ̀ sú ìfé ní
agbolé tí ìgbóná bá wọ̀.
ii. Bí òòrùn bá mú, a kò gbọdọ̀ lu ìlù/agolo/irin/páànù nínú ilé tí ìgbóná bá wọ̀.
iii.A kò gbọdọ̀ fi Ṣànpọ̀nná búra lórí irọ́.
iv.A kò gbọdọ̀ fi abẹ fá orí ẹni tí Ṣànpọ̀nná (ìgbóná) bá yọ ní ara rẹ̀.
v. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fi ọwọ̀/ìgbálẹ̀ gbálẹ̀ nínú ilé tí ìgboná bá
wọ̀.
vi. A kò gbọdọ̀ sunkún níbi òkú ẹni tí Ṣànpọ̀nná bá pa.
vii. A kò gbọdọ̀ sin òkú ẹni tí Ṣànpọ̀nná bá pa sí inú ilé.
- Èṣù: i. A kò gbọdọ̀ gbé àdí dé ìdí/ojúbọ Èṣù.
ii. A kò gbọdọ̀ fi iṣu ìgángánrán gún iyán láti bọ Èṣù.
iii. A kò gbọdọ̀ fi ìgbín bọ Èṣù.
iv. A kò gbọdọ̀ mú nínú èkìrì ẹran tí a fi bọ Èṣù wọ inú ilé.
v. Fìlà kò gbọdọ̀ ṣí sẹ́yìn bọ́ sílẹ̀ lórí Ẹlẹ́rẹ̀ẹ́ Èṣù.
vi. Ẹlẹ́rẹ̀ẹ́ Èṣù kò gbọdọ̀ pe òkèlè ní òkèlè
(ọ̀wẹ ni ó máa pè é)
vii. A kò gbọdọ̀ fi ẹ̀rẹ́ Èṣù dọ̀bálẹ̀ fún ọba ìlú.
- Ìbejì: i. Wọn kò gbọdọ̀ ṣe nǹkan fún Táyé kí wọ́n má ṣe fún
Kẹ́yìndé.
ii. Èyíkéyìí nínú àwọn òbí ìbejì kò gbọdọ̀ dágunlá lórí ìtọ́jú
wọn.
iii. Bí ọ̀kan bá kú nínú àwọn ìbejì, wọn kò gbọdọ̀ túfọ̀ rẹ̀ fún
ẹnikẹ́ni kí èkejì gbọ́.
iv. Ìbejì kì í jẹ ẹran ọ̀bọ.
(gb) Egúngún:i. Egúngún kò gbọdọ̀ wọ àgbẹ̀dẹ/ilé arọ́.
ii. Egúngún kò gbọdọ tẹ kùkù àgbàdo mọ́lẹ̀.
iii.Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ ilésanyìn (ilé tí wọ́n tọ́jú agọ̀/ẹ̀kú
eégún sí).
iv. Ènìyàn kò gbọdọ̀ rí imí egúngún.
- Agẹmọ: i. A kò gbọdọ̀ mú ajá dé ojúbọ Agẹmọ; a kò sí gbọdọ̀ fi
ajá bọ ọ́.
ii.Wọn kì í fi iyọ̀ sí oúnjẹ tí wọ́n bá máa fi yánlẹ̀ ní iwájú
Agẹmọ.
iii.Àpadárí ni wọ́n gbọdọ̀ pa ẹran tí wọ́n yóò bá fi bọ Agẹmọ.
iv.Ọ̀gbẹ̀rì kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ tí wọ́n bá fi yanlẹ̀ ní iwájú
Agẹmọ
- Ifá: i. Ọba ìlú kò gbọdọ̀ bá babaláwo jiyàn.
ii.Babaláwo tó bá ní Ìrẹ̀lẹ̀ ní ojúbọ Ifá rẹ̀ kò gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ ẹran tí ó bá pa sí ara Ifá náà, ara ère Ìrẹ̀lẹ̀ ni yóò ro ó sí.
iii. Ọ̀pá ọ̀rẹ̀rẹ̀ kò gọdọ̀ fi ẹ̀gbẹ́ kanlẹ̀ ní ojúbọ Ifá.
iv. Babaláwo kò gbọdọ̀ fi ẹran abirùn bọ Ifá.
v. Babaláwo kò gbọdọ̀ bọ Mọlẹ̀ (Ìyàwó Ọ̀rúnmìlà).
Candidates who attempted this question tackled it well.