Question 6
Níṅú ìtàn “Ajá Ọdẹ”, ṣàlàyé bí ọdẹ yìí ṣe rí ajá rẹ̀ padà.
Observation
Candidates were required to narrate how the hunter was able to find his lost dog in the folktale.
Bí ọdẹ ṣe rí ajá rẹ̀ padà:
(i) Ọkùnrin kan wà tí ó yan iṣẹ́ ọdẹ ní ààyò, ó sì gbóná nínú iṣẹ́ náà.
(ii) Ọkùnrin yìí ní ajá kan tí ó fún un lókìkí púpọ̀.
(iii) Ọkùnrin yìí fẹ́ràn ajá rẹ̀ púpọ̀, wọ́n kì í sì ya ara wọn nígbà kan.
(iv) Awọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlára ọdẹ yìí àti ajá rẹ̀.
(v) Ní ọjọ́ kan, ọdẹ yìí kò rí ajá rẹ̀ mọ́.
(vi) Níbi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá ajá yìí kiri ni ó ti gbúròó pé àwọn kan ni ó gbé ajá òun pamọ́.
(vii) Ọdẹ yìí lọ fi ẹjọ́ sun ọba ìlú wọn.
(viii) Ọba gbọ́ ó sì pe gbogbo ìlú, ọdẹ àti àwọn tí ọdẹ fura sí jọ.
(ix) Ọba pàṣẹ pé kí kálukú máa pe ajá náà bí wọ́n ṣe ń pè é tí ó fi máa ń dá wọn lóhùn.
(x) Àwọn tí wọ́n jí ajá ni wọ́n kọ́kọ́ jáde tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí pe ajá yìí.
(xi) Wọ́n pè é títí, ajá náà kò ṣe bí ẹni tí ó gbọ́ ǹnkan kan.
(xii) Lẹ́yìn náà, ọba pe ọdẹ kí ó wá pe ajá rẹ̀ bí í ti í pè é.
(xiii) Ọdẹ bá bẹ̀rẹ̀ síí fi orin pe ajá rẹ̀ báyìí pé:
Lílé: Ajá mi dà?
Ègbè: Ajá ọdẹ...
(xiv) Bí ọdẹ ti ń kọrin bẹ́ẹ̀ ni ajá bẹ̀rẹ̀ síí gbó, tí ó ń ké, tí ó sì ń gbìyànjú láti tú ara rẹ̀ sílẹ̀.
(xv) Bí ọdẹ tún ti kọrin yìí lẹ́ẹ̀kan sí i ni ajá jákùn tí ó sì ń sá tọ olówó rẹ̀ lọ.
(xvi) Àwọn ènìyàn hó gèè.
(xvii) Ọba pàṣẹ kí ọdẹ máa mú ajá rẹ̀ lọ.
(xviii) Báyìí ni ọkùnrin ọdẹ yìí ṣe rí ajá rẹ̀ padà.
The folktale of “Ajá ọdẹ” was not properly retold by most candidates, revealing a lack of proper study of the text.