Question 9
Báwo ni Òbí ṣe gba òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn síníọ̀ ibi ìkọ́ṣẹ́ tí wọ́n ń fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n?.
Observation
Candidates were expected to narrate how Obi liberated himself and his brother from the bullying seniors in their workshop.
Bí Òbí ṣe gba òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn síníọ̀ ibi ẹ̀kọ́ṣẹ́ tí wọ́n ń fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n:
- Oríṣiríṣi iṣẹ́ ìwọ̀sí àti ẹ̀gbin ni àwọn síníọ̀ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ibi ìwé títẹ̀ máa ń rán Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
- Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ju àwọn síníọ̀ wọ̀nyí lọ lọ́jọ́-orí ṣùgbọ́n torí pé wọ́ṅ ṣáájú wọn dé ẹnu ìkọ́ṣẹ́ ni wọ́n ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀.
- Ìru ìwà tí àwọn síníọ̀ yìí ń hù sí wọn ń bí Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ níṅú.
- Òbí pinnu pé òun yóò kọ ìyà yìí lọ́jọ́ kan.
- Ní àárọ̀ ọjọ́ kan, ọ̀gá tí wọ́n ń kọ́ṣẹ́ ìwé títẹ̀ ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ rán Òbí àti àwọn síníọ̀ méjì ní oko igi fún ìyàwó rẹ̀.
- Abóròdé wà lára àwọn síníọ̀ tí ọ̀gá rán lóko igi.
- Òbí ti kanrí Abóròdé sínú pé lọ́jọ́ náà ni òun yóò ṣe é fún un bí ó bá kọjá àyè rẹ̀ lóko igi.
- Ẹni kẹta wọn tí ó ń jẹ́ Jẹ́n̄bọ́lá ni ó kó wọn lọ sí oko bàbá rẹ̀ láti lọ ṣẹ́ igi.
- Bí wọ́n ti dé ọ̀hún tí wọ́n ṣẹ́gi tán, Abóròdé jókòó ó ní kí wọ́n lọ bá òun wá okùn tí òun yóò fi di igi òun.
- Òbí tètè wá okùn tirẹ̀ tán ṣáájú ẹni kẹta.
- Bí Òbí ti jáde sínú oko níbi tí igi wọ́n wà ni Abóròdé fẹ́ẹ́ gba okùn náà lọ́wọ́ rẹ̀.
- Òbí sì jẹ́ kí ó mọ̀ pé òun kò bá a wá okùn kankan.
- Ó ní kí Abóròdé wọgbó lọ kí ó lọ wá okùn tirẹ̀.
- Abóròdé sì fẹ́ fi agídí gba okùn náà lọ́wọ́ Òbí.
- Bí Òbí ṣe bú u nìyẹn pé kò ju ẹni tí òun pàápàá lè rán níṣẹ́ lọ ní ọjọ́-orí.
- Inú bí Abóròdé, ó lọ gbé igi kan nílẹ̀, pé kí òun là á mọ́ Òbí.
- Kíá, Òbí náà ti sáré já ẹgba tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó ro dáadáa.
- Òbí kò jẹ́ kí igi Abóròdé yìí ba òun.
- Kí ẹni kẹta wọn tó jáde láti inú igbó, Òbí ti la Abóròdé mọ́lẹ̀, ó sì ti kó erùpẹ̀ sí i lẹ́nu.
- Òbí ń kó ẹgba bo Abóròdé.
- Abóròdé sáré dìde, o ń sá lọ ó sì ń ké pé Òbí ti na òun pa o.
- Ìròyìn ìjà yìí kan àwọn síníọ̀ tó kù lára nílé.
- Àwọn síníọ̀ pa gbogbo ìwà ìwọ̀sí yẹn tì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí pọ́n Òbí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lé.
- Báyìí ni Òbí ṣe gba òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn síníọ̀ tí wọ́n ń fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n ní ibi ẹ̀kọ́ṣẹ́.
Few Candidates did a proper narration of the event.