Question 11
“Ohun tí kò tó ń bọ̀ wá ṣẹ́kù”, báwo ni ìpèdè yìí ṣe bá ìrírí ìdílé Kọ́lá Ẹgbẹ́dá mu.
Observation
Candidates were expected to narrate the experience of the Ẹgbẹ́dá Family in relation to the adage “ohun tí kò tó ń bọ̀ wá ṣẹ́kù”.
Bí ìpèdè “ohun tí kò tó ń bọ̀ wá ṣẹ́kù” ṣe bá ìrírí ìdílé Kọ́lá Ẹgbẹ́dá mu:
- Tálákà ni Kọ́lá Ẹgbẹ́dá àti ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ òbí Ṣọlá.
- Kọ́lá Ẹgbẹ́dá kàwé tátàtá, òṣìṣẹ́ rélùwéè ni.
- Ìyá Ṣọlá ń ta oúnjẹ fún àwọn mẹ́kàníìkì nínú ọgbà kan tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilé wọn.
- Ṣọlá tí ó jẹ́ obìnrin ni àkọ́bí, àwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jẹ́ ọkùnrin.
- Àwọn òbí Ṣọlá ń tiraka láti rán àwọn ọmọ wọn nílé-ẹ̀kọ́ kí àwọn náà lè di ènìyàn lọ́jọ́ iwájú.
- Ìyá Ṣọlá ni ó ń bọ́ gbogbo ilé wọn fún bí oṣù mọ́kànlá tí ọkọ rẹ̀ kò fi rí owó oṣù gbà.
- Gbogbo ìgbà ni ìyá Ṣọlá máa ń gbà ọkọ rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí àwọn máa forí tì í, pé ọ̀la wọn ń bọ̀ wá dára.
- Ṣọlá máa ń lo owó ọjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí ó ń tà nílé-ẹ̀kọ́ yunifásítì láti dín ìnáwó àwọn òbí rẹ̀ kù lórí rẹ̀.
- Ọlọ́run gbé Ṣọlá pàdé Fẹ́mi Johnson tí ó jẹ́ ọmọ olówó.
- Torí pé Ṣọlá jẹ́ ọmọlúàbí tí ó lẹ́kọ̀ọ́, Fẹ́mi dẹnu ìfẹ́ kọ ọ́; Ṣọlá sì gbà.
- Ìgbéyàwó Ṣọlá àti Fẹ́mi ni ó yí ìgbésí ayé ìdílé Kọ́lá Ẹgbẹ́dá padà.
- Ẹ̀bùn tí àwọn ẹbí Fẹ́mi kó wá fún ẹbí Ṣọlá lásìkò tí ẹbí méjèèjí ń ṣe mọ̀-mí-n̄-mọ̀-ọ́ ju ẹrù ìdána ẹlòmíràn lọ.
- Ìlú Òyìnbó ni Ṣọlá àti Fẹ́mi ti ra gbogbo ohun tí ọkọ àti ìyàwó lò lọ́jọ́ ìdána àti ní ọjọ́ ìgbéyàwó.
- Fẹ́mi ṣí àkáùntì fún Ṣọlá, ó sì fí ìdajì mílíọ̀ọ̀nù Náírà sínú rẹ̀ kí àwọn òbí Ṣọlá má lè ráhùn owó láti fi ṣe ti ìgbéyàwó wọn.
- Fẹ́mi tún ń san owó ilé-ẹ̀kọ́ àwọn àbúrò Ṣọlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
- Fẹ́mi ran àwọn òbí Ṣọlá lọ́wọ́ látị parí ilé tí wọ́n ti kọ́ ní àkọ́patì kí ọjọ́ ìgbeyàwó tó dé.
- Orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà ni Ṣọlá àti Fẹ́mi ti lọ sinmi fún ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn.
- Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Tòyótà Kámúrì dẹ̀ǹdẹ̀ tuntun kan ni àwọn òbí Fẹ́mi fi ta àwọn òbí Ṣọlá lọ́rẹ torí pé odindi ọmọ ni wọ́n fún àwọn.
- Báyìí ni ohun tí kò tó tẹ́lẹ̀ fún ìdílé Kọ́lá Ẹgbẹ́dá wá tó tí ó sì tún ṣẹ́kù.
Candidates’ who attempted this question exhibited a good knowledge of the set text.
.