Question 12
Kí ni àrokò?Sọ ìtumọ̀ àwọn àrokò wọ̀nyí bí a bá fi ránṣẹ́ sí ènìyàn.
Observation
Candidates were expected to define non-verbal communication in (a) and give the correct meaning of each non-verbal communication symbol in (b).
- Àrokò ni ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ nípa lílo ohun kan tàbí àmì tí ó ní ìtumọ̀ kan náà sí olùsọ̀rọ̀ àti olùgbọ́ láì lò ọ̀rọ ẹnu.
(b)
|
ÀROKÒ |
ÌTUMỌ̀ ÀROKÒ |
i |
Owó ẹyọ mẹ́ta |
Ẹni tí a fi pàrokò ránṣẹ́ sí ti di ẹni ìtanù fún ẹni tó pàrokò ránṣẹ́ sí i. |
ii |
Àjókù òwú |
Ewu kò jìnnà sí ẹni tí fi ránṣẹ́ sí. |
iii |
Awọ ehoro |
Ẹni tí a fi ránṣẹ́ sí gbọ́dọ̀ máa sá lọ. |
iv |
Orógbó |
Nǹkan ò lọ déédéé mọ́ ní ilé ẹni tí ó fi orógbó ránṣẹ́ sí ẹlòmíràn. |
v |
Ìkarahun ìgbín |
Ọkàn ẹni tí ó pa àrokò náà ń fà sí ẹni tí a pa àrokò náà ránṣẹ́ sí/tí a bá fi pa aàlè, ó túmọ̀ sí pé ẹni tí ó bá jí nǹkan náà gbé yóò kú tàbí kí ó di ìdàkudà. |
vi |
Kàn-ìn kàn-ìn |
Ìyàwó ẹni tí a fi ránṣẹ́ sí ti bímọ. |
vii |
Awẹ́ obì |
Ọ̀rọ̀ àsọtì tí ó wà láàárín ẹni tí a pa àrokò ránṣẹ́ sí àti ẹni tí ó fi àrokò ránṣẹ́ ti yanjú. |
viii |
Ìlẹ̀pa |
Òkú kú fún ẹni tí a pa àrokò yìí ránṣẹ́ si. |
Candidates’ performance was fairly good.
.